We are Still Working on our Online Web Version, Kindly Check Later!

Rutu 01

Elimeleki ati Idile rẹ̀ lọ lati máa gbe ni Moabu

1. O si ṣe li ọjọ́ wọnni ti awọn onidajọ nṣe olori, ìyan kan si mu ni ilẹ na. ọkunrin kan lati Betilehemu-juda si lọ ṣe atipo ni ilẹ Moabu, on, ati obinrin rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin meji. 2. Orukọ ọkunrin na a si ma jẹ́ Elimeleki, orukọ obinrin rẹ̀ a si ma jẹ́ Naomi, orukọ awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeji a si ma jẹ́ Maloni ati Kilioni, awọn ara Efrata ti Betilehemu-juda. Nwọn si wá si ilẹ Moabu, nwọn si ngbé ibẹ̀. 3. Elimeleki ọkọ Naomi si kú; o si kù on, ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeji. 4. Nwọn si fẹ́ aya ninu awọn obinrin Moabu; orukọ ọkan a ma jẹ́ Orpa, orukọ ekeji a si ma jẹ́ Rutu: nwọn si wà nibẹ̀ nìwọn ọdún mẹwa. 5. Awọn mejeji, Maloni ati Kilioni, si kú pẹlu; obinrin na li o si kù ninu awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeji ati ọkọ rẹ̀.

Náómì àti Rutu Padà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù

6. Nigbana li o dide pẹlu awọn aya-ọmọ rẹ̀, ki o le pada lati ilẹ Moabu wá: nitoripe o ti gbọ́ ni ilẹ Moabu bi OLUWA ti bẹ̀ awọn enia rẹ̀ wò ni fifi onjẹ fun wọn. 7. O si jade kuro ni ibi ti o gbé ti wà, ati awọn aya-ọmọ rẹ̀ mejeji pẹlu rẹ̀; nwọn si mu ọ̀na pọ̀n lati pada wá si ilẹ Juda. 8. Naomi si wi fun awọn aya-ọmọ rẹ̀ mejeji pe, Ẹ lọ, ki olukuluku pada lọ si ile iya rẹ̀: ki OLUWA ki o ṣe rere fun nyin, gẹgẹ bi ẹnyin ti ṣe fun awọn okú, ati fun mi. 9. Ki OLUWA ki o fi fun nyin ki ẹnyin le ri isimi, olukuluku nyin ni ile ọkọ rẹ̀. Nigbana li o fi ẹnu kò wọn lẹnu; nwọn si gbé ohùn wọn soke nwọn si sọkun. 10. Nwọn si wi fun u pe, Nitõtọ awa o bá ọ pada lọ sọdọ awọn enia rẹ. 11. Naomi si wipe, Ẹnyin ọmọbinrin mi ẹ pada: ẽṣe ti ẹnyin o fi bá mi lọ? mo ha tun ní ọmọkunrin ni inu mi, ti nwọn iba fi ṣe ọkọ nyin? 12. Ẹ pada, ẹnyin ọmọbinrin mi, ẹ ma lọ; nitori emi di arugbo jù ati ní ọkọ. Bi emi wipe, Emi ní ireti, bi emi tilẹ ní ọkọ li alẹ yi, ti emi si bi ọmọkunrin; 13. Ẹnyin ha le duro dè wọn titi nwọn o fi dàgba? Ẹnyin o le duro dè wọn li ainí ọkọ? Rara o, ẹnyin ọmọbinrin mi; nitoripe inu mi bàjẹ́ gidigidi nitori nyin, ti ọwọ́ OLUWA fi jade si mi. 14. Nwọn si gbé ohùn wọn soke, nwọn si tun sọkun: Orpa si fi ẹnu kò iya-ọkọ rẹ̀ lẹnu; ṣugbọn Rutu fàmọ́ ọ. 15. On si wipe, Kiyesi i, orogun rẹ pada sọdọ awọn enia rẹ̀, ati sọdọ oriṣa rẹ̀: iwọ pada tẹlé orogun rẹ. 16. Rutu si wipe, Máṣe rọ̀ mi lati fi ọ silẹ, tabi lati pada kuro lẹhin rẹ: nitori ibiti iwọ ba lọ, li emi o lọ; ibiti iwọ ba si wọ̀, li emi o wọ̀: awọn enia rẹ ni yio ma ṣe enia mi, Ọlọrun rẹ ni yio si ma ṣe Ọlọrun mi: 17. Ibiti iwọ ba kú li emi o kú si, nibẹ̀ li a o si sin mi: ki OLUWA ki o ṣe bẹ̃ si mi, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu, bi ohun kan bikoṣe ikú ba yà iwọ ati emi. 18. Nigbati on ri pe o ti pinnu rẹ̀ tán lati bá on lọ, nigbana li o dẹkun ọ̀rọ ibá a sọ. 19. Bẹ̃ni awọn mejeji lọ titi nwọn fi dé Betilehemu. O si ṣe, ti nwọn dé Betilehemu, gbogbo ilu si dide nitori wọn, nwọn si wipe, Naomi li eyi? 20. On si wi fun wọn pe, Ẹ má pè mi ni Naomi mọ́, ẹ mã pè mi ni Mara: nitoriti Olodumare hùwa kikorò si mi gidigidi. 21. Mo jade lọ ni kikún, OLUWA si tun mú mi pada bọ̀wá ile li ofo: ẽhaṣe ti ẹnyin fi npè mi ni Naomi, nigbati OLUWA ti jẹritì mi, Olodumare si ti pọn mi loju? 22. Bẹ̃ni Naomi padawá, ati Rutu ara Moabu, aya-ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ẹniti o ti ilẹ Moabu wá; nwọn si wá si Beti-lehemu ni ìbẹrẹ ikore ọkà-barle.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *