We are Still Working on our Online Web Version, Kindly Check Later!

Lefitiku 01

Àwọn Ẹbọ Tí A Sun Lódidi

1. OLUWA si pè Mose, o si sọ fun u lati inu agọ́ ajọ wa, pe, 2. Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Bi ẹnikan ninu nyin ba mú ọrẹ-ẹbọ wá fun OLUWA, ki ẹnyin ki o mú ọrẹ-ẹbọ nyin wá ninu ohunọ̀sin, ani ti inu ọwọ́-ẹran, ati ti agbo-ẹran. 3. Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba ṣe ẹbọ sisun ti inu ọwọ́-ẹran, ki on ki o mú akọ wá alailabùku: ki o mú u wá tinutinu rẹ̀ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ siwaju OLUWA. 4. Ki o si fi ọwọ rẹ̀ lé ori ẹbọ sisun na; yio si di itẹwọgbà fun u lati ṣètutu fun u. 5. Ki o si pa akọmalu na niwaju OLUWA: awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, yio si mú ẹ̀jẹ na wá, nwọn o si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ nì yiká ti mbẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 6. Ki o si bó ẹbọ sisun na; ki o si kun u. 7. Awọn ọmọ Aaroni alufa ni yio si fi iná sori pẹpẹ na, nwọn o si tò igi lori iná na: 8. Awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni yio si tò ninu rẹ̀, ani ori ati ọrá wọn sori igi ti mbẹ lori iná, ti mbẹ lori pẹpẹ: 9. Ṣugbọn ifun rẹ̀, ati itan rẹ̀ ni ki o ṣàn ninu omi: ki alufa ki o si sun gbogbo rẹ̀ lori pẹpẹ na lati ṣe ẹbọ sisun, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA. 10. Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ti agbo-ẹran, eyinì ni ti agutan, tabi ti ewurẹ, fun ẹbọ sisun; akọ ni ki o múwa alailabùku. 11. Ki o si pa a niwaju OLUWA li ẹba pẹpẹ ni ìha ariwa: ati awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni yio si bù ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ na yiká. 12. Ki o si kun u, ori rẹ̀ ati ọrá rẹ̀: alufa na yio si tò wọn sori igi ti mbẹ lori iná ti mbẹ lori pẹpẹ: 13. Ṣugbọn ki o ṣìn ifun ati itan rẹ̀ ninu omi: ki alufa na ki o si mú gbogbo rẹ̀ wá, ki o si sun u lori pẹpẹ: ẹbọ sisun ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA. 14. Bi o ba si ṣepe ti ẹiyẹ ni ẹbọ sisun ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ si OLUWA, njẹ ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá ninu àdaba, tabi ninu ọmọ ẹiyẹle. 15. Ki alufa na ki o si mú u wá si pẹpẹ na, ki o si mi i li ọrùn, ki o si sun u lori pẹpẹ na; ẹ̀jẹ rẹ̀ ni ki o si ro si ẹba pẹpẹ na. 16. Ki o si fà ajẹsi rẹ̀ já pẹlu ẽri rẹ̀, ki o si kó o lọ si ẹba pẹpẹ na ni ìha ìlà-õrùn, lori ibi ẽru nì: 17. Ki o si là a ti on ti iyẹ́-apa rẹ̀, ṣugbọn ki yio pín i ni meji jalẹ: ki alufa ki o si sun u lori pẹpẹ na, lori igi na ti mbẹ lori iná: ẹbọ sisun ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *