We are Still Working on our Online Web Version, Kindly Check Later!

Joshua 01

Ọlọrun Pàṣẹ fún Joṣua pé Kí Ó Fi Ogun Kó Ilẹ̀ Kenaani

1. O si ṣe lẹhin ikú Mose iranṣẹ OLUWA, li OLUWA sọ fun Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ Mose, wipe, 2. Mose iranṣẹ mi kú; njẹ iwọ, dide, gòke Jordani yi, iwọ, ati gbogbo enia yi, si ilẹ ti mo fi fun wọn, ani fun awọn ọmọ Israeli. 3. Ibi gbogbo ti atẹlẹsẹ̀ nyin ba tẹ̀, ẹnyin ni mo fi fun, gẹgẹ bi mo ti sọ fun Mose. 4. Lati aginjù, ati Lebanoni yi, ani titi dé odò nla nì, odò Euferate, gbogbo ilẹ awọn Hitti, ati titi dé okun nla ni ìwọ-õrùn, eyi ni yio ṣe opin ilẹ nyin. 5. Ki yio sí ọkunrin kan ti yio le duro niwaju rẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo: gẹgẹ bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹ̃li emi o si wà pẹlu rẹ: Emi ki yio fi ọ silẹ, bẹ̃li emi ki yio kọ̀ ọ. 6. Ṣe giri, ki o si mu àiya le: nitori iwọ ni yio pín ilẹ na fun awọn enia yi, ilẹ ti mo ti bura fun awọn baba wọn lati fi fun wọn. 7. Sá ṣe giri ki o si mu àiya le gidigidi, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo ofin ti Mose iranṣẹ mi ti palaṣẹ fun ọ: má ṣe yà kuro ninu rẹ̀ si ọtún tabi si òsi, ki o le dara fun ọ nibikibi ti iwọ ba lọ. 8. Iwé ofin yi kò gbọdọ kuro li ẹnu rẹ, ṣugbọn iwọ o ma ṣe àṣaro ninu rẹ̀ li ọsán ati li oru, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọ sinu rẹ̀: nitori nigbana ni iwọ o ṣe ọ̀na rẹ ni rere, nigbana ni yio si dara fun ọ. 9. Emi kò ha paṣẹ fun ọ bi? Ṣe giri ki o si mu àiya le; máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya ki o máṣe fò ọ: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ nibikibi ti iwọ ba nlọ.

Joṣua Pàṣẹ fún Àwọn Eniyan Náà

10. Nigbana ni Joṣua paṣẹ fun awọn olori awọn enia wipe, 11. Ẹ là ãrin ibudó já, ki ẹ si paṣẹ fun awọn enia, wipe, Ẹ pèse onjẹ; nitoripe ni ijọ́ mẹta oni ẹnyin o gòke Jordani yi, lati lọ gbà ilẹ ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin lati ní. 12. Ati fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse, ni Joṣua wipe, 13. Ranti ọ̀rọ ti Mose iranṣẹ OLUWA palaṣẹ fun nyin pe, OLUWA Ọlọrun nyin nfun nyin ni isimi, on o si fun nyin ni ilẹ yi. 14. Awọn obinrin nyin, ati awọn ọmọ wẹrẹ nyin, ati ohunọ̀sin nyin, yio joko ni ilẹ ti Mose fi fun nyin ni ìha ihin Jordani; ṣugbọn ẹnyin o gòke lọ niwaju awọn arakunrin nyin ni ihamọra, gbogbo awọn alagbara akọni, ẹnyin o si ràn wọn lọwọ, 15. Titi OLUWA yio fi fun awọn arakunrin nyin ni isimi, gẹgẹ bi o ti fi fun nyin, ati ti awọn pẹlu yio fi gbà ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun wọn: nigbana li ẹnyin o pada si ilẹ iní nyin, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun nyin ni ìha ihin Jordani ni ìha ìla-õrùn, ẹnyin o si ní i. 16. Nwọn si da Joṣua lohùn, wipe, Gbogbo ohun ti iwọ palaṣẹ fun wa li awa o ṣe, ibikibi ti iwọ ba rán wa lọ, li awa o lọ. 17. Gẹgẹ bi awa ti gbọ́ ti Mose li ohun gbogbo, bẹ̃li awa o gbọ́ tirẹ: kìki ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o wà pẹlu rẹ, gẹgẹ bi o ti wà pẹlu Mose. 18. Ẹnikẹni ti o wù ki o ṣe ti o ba tapá si ofin rẹ, ti ki yio si gbọ́ ọ̀rọ rẹ li ohun gbogbo ti iwọ palaṣẹ fun u, pipa li a o pa a: kìki ki iwọ ṣe giri ki o si mu àiya le.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *