We are Still Working on our Online Web Version, Kindly Check Later!

Habakkuku 01

1. Ọ̀rọ-ìmọ ti Habakuku wolii rí.

Ìṣubú Ninefe

2. Oluwa, emi o ti ke pẹ to, ti iwọ kì yio fi gbọ́! ti emi o kigbe si ọ, niti ìwa-ipa, ti iwọ kì yio si gbalà! 3. Ẽṣe ti o mu mi ri aiṣedede, ti o si jẹ ki nma wò ìwa-ìka? nitori ikógun ati ìwa-ipá wà niwaju mi: awọn ti si nrú ijà ati ãwọ̀ soke mbẹ. 4. Nitorina li ofin ṣe di ẹ̀rọ, ti idajọ kò si jade lọ li ẹtọ́; nitoriti ẹni buburu yí olododo ka; nitorina ni idajọ ẹbi ṣe njade.

Ìdáhùn Ọlọrun

5. Ẹ wò inu awọn keferi, ki ẹ si wò o, ki hà ki o si ṣe nyin gidigidi: nitoriti emi o ṣe iṣẹ kan li ọjọ nyin, ti ẹ kì yio si gbagbọ́, bi a tilẹ sọ fun nyin. 6. Nitoripe, wò o, emi gbe awọn ara Kaldea dide, orilẹ-ède ti o korò, ti o si yára, ti yio rìn ibú ilẹ na ja, lati ni ibùgbe wọnni, ti kì iṣe ti wọn. 7. Nwọn ni ẹ̀ru, nwọn si fò ni laiyà: idajọ wọn, ati ọlanla wọn, yio ma ti inu wọn jade. 8. Ẹṣin wọn pẹlu yara jù ẹkùn lọ, nwọn si muná jù ikõkò aṣãlẹ lọ: ẹlẹṣin wọn yio si tàn ara wọn ka, ẹlẹṣin wọn yio si ti ọ̀na jijìn rére wá; nwọn o si fò bi idì ti nyára lati jẹun. 9. Gbogbo wọn o si wá fun ìwa-ipá; iwò oju wọn o si wà siwaju, nwọn o si kó igbèkun jọ bi yanrìn. 10. Nwọn o si ma fi awọn ọba ṣẹsín, awọn ọmọ alade yio si di ẹni-ẹ̀gan fun wọn: gbogbo ibi agbara ni nwọn o si fi rẹrin; nitoripe nwọn o ko erupẹ̀ jọ, nwọn o si gbà a. 11. Nigbana ni inu rẹ̀ yio yipadà, yio si rekọja, yio si ṣẹ̀, ni kikà agbara rẹ̀ yi si iṣẹ òriṣa rẹ̀.

Habakuku tún Ráhùn sí OLUWA

12. Lati aiyeraiye ki iwọ ti wà? Oluwa Ọlọrun mi, Ẹni Mimọ́ mi? awa kì yio kú. Oluwa, iwọ ti yàn wọn fun idajọ; Ọlọrun alagbara, iwọ ti fi ẹsẹ̀ wọn mulẹ fun ibawi. 13. Oju rẹ mọ́ jù ẹniti iwò ibi lọ, iwọ kò si lè wò ìwa-ìka: nitori kini iwọ ha ṣe nwò awọn ti nhùwa arekerekè, ti o si pa ẹnu rẹ mọ, nigbati ẹni-buburu jẹ ẹniti iṣe olododo jù u run? 14. Ti iwọ si nṣe enia bi ẹja okun, bi ohun ti nrakò, ti kò ni alakoso lori wọn? 15. Iwọ ni àwọn lati fi gbé gbogbo wọn, nwọn nfi àwọn mu wọn, nwọn si nfi awò wọn kó wọn: nitorina ni nwọn ṣe nyọ̀, ti inu wọn si ndùn. 16. Nitorina, nwọn nrubọ si àwọn wọn, nwọn si nsùn turari fun awò wọn; nitori nipa wọn ni ipin wọn ṣe li ọrá, ti onjẹ wọn si fi di pupọ̀. 17. Nitorina, nwọn o ha ma dà àwọn wọn, nwọn kì yio ha dẹkun lati ma fọ́ orilẹ-ède gbogbo?

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *