We are Still Working on our Online Web Version, Kindly Check Later!

Genesisi 01

Ìtàn bí a ṣe dá ayé

1. Ní atetekọṣe Ọlọrun dá ọrun ati aiye. 2. Aiye si wà ni jũju, o si ṣofo; òkunkun si wà loju ibú: Ẹmi Ọlọrun si nràbaba loju omi. 3. Ọlọrun si wipe, Ki imọlẹ ki o wà: imọlẹ si wà. 4. Ọlọrun si ri imọlẹ na, pe o dara: Ọlọrun si pàla si agbedemeji imọlẹ ati òkunkun. 5. Ọlọrun si pè imọlẹ ni Ọsán, ati òkunkun ni Oru. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kini. 6. Ọlọrun si wipe, Ki ofurufu ki o wà li agbedemeji omi, ki o si yà omi kuro lara omi. 7. Ọlọrun si ṣe ofurufu, o si yà omi ti o wà nisalẹ ofurufu kuro lara omi ti o wà loke ofurufu: o si ri bẹ̃. 8. Ọlọrun si pè ofurufu ni Ọrun. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ keji. 9. Ọlọrun si wipe, Ki omi abẹ ọrun ki o wọjọ pọ̀ si ibi kan, ki iyangbẹ ilẹ ki o si hàn: o si ri bẹ̃. 10. Ọlọrun si pè iyangbẹ ilẹ ni Ilẹ; o si pè iwọjọpọ̀ omi ni Okun: Ọlọrun si ri pe o dara. 11. Ọlọrun si wipe, Ki ilẹ ki o hù oko, eweko ti yio ma so eso, ati igi eleso ti yio ma so eso ni irú tirẹ̀, ti o ni irugbin ninu lori ilẹ: o si ri bẹ̃. 12. Ilẹ si sú koriko jade, eweko ti nso eso ni irú tirẹ̀, ati igi ti nso eso, ti o ni irugbin ninu ni irú tirẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara. 13. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹta. 14. Ọlọrun si wipe, Ki awọn imọlẹ ki o wà li ofurufu ọrun, lati pàla ọsán on oru; ki nwọn ki o si ma wà fun àmi, ati fun akoko, ati fun ọjọ́, ati fun ọdún: 15. Ki nwọn ki o si jẹ́ imọlẹ li ofurufu ọrun, lati mọlẹ sori ilẹ: o si ri bẹ̃. 16. Ọlọrun si dá imọlẹ nla meji; imọlẹ ti o tobi lati ṣe akoso ọsán, ati imọlẹ ti o kere lati ṣe akoso oru: o si dá awọn irawọ pẹlu. 17. Ọlọrun si sọ wọn lọjọ̀ li ofurufu ọrun, lati ma tàn imọlẹ sori ilẹ, 18. Ati lati ṣe akoso ọsán ati akoso oru, ati lati pàla imọlẹ on òkunkun: Ọlọrun si ri pe o dara. 19. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹrin. 20. Ọlọrun si wipe, Ki omi ki o kún fun ọ̀pọlọpọ ẹdá alãye ti nrakò, ati ki ẹiyẹ ki o ma fò loke ilẹ li oju-ofurufu ọrun. 21. Ọlọrun si dá erinmi nlanla ati ẹdá alãye gbogbo ti nrakò, ti omi kún fun li ọ̀pọlọpọ ni irú wọn, ati ẹiyẹ abiyẹ ni irú rẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara. 22. Ọlọrun si súre fun wọn pe, Ẹ ma bi si i, ẹ si mã rẹ̀, ki ẹ kún inu omi li okun, ki ẹiyẹ ki o si ma rẹ̀ ni ilẹ. 23. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ karun. 24. Ọlọrun si wipe, Ki ilẹ ki o mu ẹdá alãye ni irú rẹ̀ jade wá, ẹran-ọ̀sin, ati ohun ti nrakò, ati ẹranko ilẹ ni irú rẹ̀: o si ri bẹ̃. 25. Ọlọrun si dá ẹranko ilẹ ni irú tirẹ̀, ati ẹran-ọ̀sin ni irú tirẹ̀, ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ni irú tirẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara. 26. Ọlọrun si wipe, Jẹ ki a dá enia li aworan wa, gẹgẹ bi irí wa: ki nwọn ki o si jọba lori ẹja okun, ati lori ẹiyẹ oju-ọrun, ati lori ẹranko, ati lori gbogbo ilẹ, ati lori ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ. 27. Bẹ̃li Ọlọrun dá enia li aworan rẹ̀, li aworan Ọlọrun li o dá a; ati akọ ati abo li o dá wọn. 28. Ọlọrun si súre fun wọn. Ọlọrun si wi fun wọn pe, Ẹ ma bi si i, ki ẹ si ma rẹ̀, ki ẹ si gbilẹ, ki ẹ si ṣe ikawọ rẹ̀; ki ẹ si ma jọba lori ẹja okun, ati lori ẹiyẹ oju-ọrun, ati lori ohun alãye gbogbo ti nrakò lori ilẹ. 29. Ọlọrun si wipe, kiye si i, Mo fi eweko gbogbo ti o wà lori ilẹ gbogbo ti nso eso fun nyin, ati igi gbogbo ninu eyiti iṣe igi eleso ti nso; ẹnyin ni yio ma ṣe onjẹ fun. 30. Ati fun gbogbo ẹranko ilẹ, ati fun gbogbo ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun ohun gbogbo ti o nrakò lori ilẹ, ti iṣe alaye, ni mo fi eweko tutu gbogbo fun li onjẹ: o si ri bẹ̃. 31. Ọlọrun si ri ohun gbogbo ti o dá, si kiyesi i, daradara ni. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹfa.

 

20 Comments

 • I can not find The book of Zephaniah in your Yoruba audio bible also all the book can’t download please do something about it. I really thank God for your life and what He his using you for May He continued strengthen you.

  Mrs Okegbenro Reply
  • thanks for your comment, on our app its called SEFANIAH and it’s available. The bible books are downloading as show on video

   Sanmi Ajanaku Reply
 • Dear Sir/Ma, I , just bought your offline audio bible Yoruba and paid via online but it’s been very difficult downloading and hearing the audio work.

  Rachael Olaleye Reply
 • Your comment …

  Rachael Olaleye Reply
 • Offline audio bought not working

  Rachael Olaleye Reply
 • The Yoruba audio bible just downloaded is not speaking, why?

  Jimoh Abiodun Reply
 • How can I download Yoruba bible please can you really help me for it

  Adewaleola Reply
 • thank you for bringing gospel to us online

  john Reply
 • I purchased the Yoruba audio bible 3days ago and it’s not working audibly please I would like a quick solution to this as I have already sent an email. Looking forward to receive an immediate response. Thanks

  Oladele Reply
  • thanks for your email, am glad the app is now working, next time check yorubabible.net/contact/

   Sanmi Ajanaku Reply
 • Your comment …

  Bola Valentine Reply
  • We understand the issue and we are now working on making the app completely free.

   Sanmi Ajanaku Reply
 • I want to pay for this Yoruba audio Bible but could not with my master card. What is d alternative?

  Atoyebi Samson Reply
  • Hello atoyebi, we are trying and working to make this app free very soon. Please bear some patience.

   Sanmi Ajanaku Reply
 • how can i download the audio?

  MARY OSENI Reply
 • Please what could be the problem? I have been trying all day to make payment for the purchase. I have used 2 cards but it’s not accepting any. Waiting for your advice.

  Jane Mola Reply
  • Hello, its not your card or our app, its google’s payment that makes it so difficult, we are so sorry, you are facing this problem, we are working to make the app completely free very soon.

   Sanmi Ajanaku Reply
 • God will bless your work. how do i download?

  SOYELE ABIODUN Reply

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *