We are Still Working on our Online Web Version, Kindly Check Later!

Mika 06

Ọlọrun bá Israẹli Rojọ́

1. Ẹ gbọ́ nisisiyi ohun ti Oluwa wi; Dide, ba oke nla wijọ, si jẹ ki oke kékèké gbohùn rẹ. 2. Ẹ gbọ́ ẹjọ Oluwa, ẹnyin oke-nla, ati ẹnyin ipilẹ ilẹ̀ aiye: nitori Oluwa mba awọn enia rẹ̀ wijọ, yio si ba Israeli rojọ. 3. Enia mi, kini mo fi ṣe ọ? ati ninu kini mo fi da ọ li agara? dahùn si i. 4. Nitori mo ti mu ọ goke lati ilẹ Egipti wá, mo si rà ọ padà lati ile ẹrú wá; mo si rán Mose, Aaroni, ati Miriamu siwaju rẹ. 5. Enia mi, ranti nisisiyi ohun ti Balaki ọba Moabu gbèro, ati ohun ti Balaamu ọmọ Beori dá a lohùn lati Ṣittimu titi de Gilgali; ki ẹ ba le mọ̀ ododo Oluwa.

Ohun Tí OLUWA Fẹ́ Kí Á Ṣe

6. Kini emi o ha mu wá siwaju Oluwa, ti emi o fi tẹ̀ ara mi ba niwaju Ọlọrun giga? ki emi ha wá siwaju rẹ̀ pẹlu ọrẹ-ẹbọ sisun, pẹlu ọmọ malu ọlọdún kan? 7. Inu Oluwa yio ha dùn si ẹgbẹgbẹ̀run àgbo, tabi si ẹgbẹgbãrun iṣàn òroro? emi o ha fi àkọbi mi fun irekọja mi, iru-ọmọ inu mi fun ẹ̀ṣẹ ọkàn mi? 8. A ti fi hàn ọ, Iwọ enia, ohun ti o dara; ati ohun ti Oluwa bère lọwọ rẹ, bikoṣe ki o ṣe otitọ, ki o si fẹ ãnu, ati ki o rìn ni irẹ̀lẹ pẹlu Ọlọrun rẹ? 9. Ohùn Oluwa kigbe si ilu na, ọlọgbọ́n yio si ri orukọ rẹ; ẹ gbọ́ ọ̀pa na, ati ẹniti o yàn a? 10. Iṣura ìwa buburu ha wà ni ile enia buburu sibẹ̀, ati òṣuwọ̀n aikún ti o jẹ ohun ibinú? 11. Ki emi ha kà wọn si mimọ́ pẹlu òṣuwọ̀n buburu, ati pẹlu àpo òṣuwọ̀n ẹ̀tan? 12. Ti awọn ọlọrọ̀ rẹ̀ kún fun ìwa-ipá, ati awọn ti ngbe inu rẹ̀ ti sọ̀rọ eké, ahọn wọn si kún fun ẹ̀tan li ẹnu wọn. 13. Nitorina pẹlu li emi o ṣe mu ọ ṣàisan ni lilù ọ, ni sisọ ọ dahoro nitori ẹ̀ṣẹ rẹ. 14. Iwọ o jẹun, ṣugbọn iwọ kì yio yo; idábẹ yio wà lãrin rẹ; iwọ o kó kuro, ṣugbọn iwọ kì o lọ lailewu; ati eyi ti o kó lọ li emi o fi fun idà. 15. Iwọ o gbìn, ṣugbọn iwọ kì yio ká; iwọ o tẹ̀ igi olifi, ṣugbọn iwọ kì o fi ororo kunra; ati eso àjara, sugbọn iwọ kì o mu ọti-waini. 16. Nitori ti a pa aṣẹ Omri mọ́, ati gbogbo iṣẹ ile Ahabu, ẹ si rìn ni ìmọ wọn; ki emi ba le sọ ọ di ahoro, ati awọn ti ngbe inu rẹ di ẹ̀gan: ẹnyin o si rù ẹgan enia mi.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *