We are Still Working on our Online Web Version, Kindly Check Later!

Mika 04

Ìjọba Alaafia OLUWA Tí Ó Kárí Ayé

1. YIO si ṣe li ọjọ ikẹhìn, a o fi oke ile Oluwa kalẹ lori awọn oke-nla, a o si gbe e ga jù awọn oke kekeke lọ; awọn enia yio si mã wọ́ sinu rẹ̀. 2. Ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède yio si wá, nwọn o si wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a goke lọ si oke-nla Oluwa, ati si ile Ọlọrun Jakobu; on o si kọ́ wa li ọ̀na rẹ̀, awa o si ma rìn ni ipa-ọ̀na rẹ̀: nitori lati Sioni ni ofin yio ti jade lọ, ati ọ̀rọ Oluwa lati Jerusalemu. 3. On o si ṣe idajọ lãrin ọ̀pọlọpọ enia, yio si bá alagbara orilẹ-ède rére wi; nwọn o si fi idà wọn rọ ọbẹ irin-itulẹ̀, ati ọ̀kọ wọn rọ dojé: orilẹ-ède kì yio gbe idà soke si orilẹ-ède, bẹ̃ni nwọn kì yio kọ́ ogun jijà mọ. 4. Ṣugbọn nwọn o joko olukuluku labẹ ajara rẹ̀ ati labẹ igi ọpọtọ rẹ̀; ẹnikan kì yio si daiyà fò wọn: nitori ẹnu Oluwa awọn ọmọ-ogun li o ti sọ ọ. 5. Nitori gbogbo awọn enia ni yio ma rìn, olukuluku li orukọ ọlọrun tirẹ̀, awa o si ma rìn li orukọ Oluwa Ọlọrun wa lai ati lailai.

Israẹli Yóo Pada láti Oko Ẹrú

6. Li ọjọ na, ni Oluwa wi, li emi o kó amukun, emi o si ṣà ẹniti a le jade, ati ẹniti emi ti pọn loju jọ; 7. Emi o si dá awọn amukun si fun iyokù, emi o si sọ ẹniti a ta nù rére di orilẹ-ède alagbara: Oluwa yio si jọba lori wọn li oke-nla Sioni lati isisiyi lọ, ati si i lailai. 8. Ati iwọ, Ile iṣọ agbo agùtan, odi ọmọbinrin Sioni, si ọdọ rẹ ni yio wá, ani ijọba iṣãju; ijọba yio si wá si ọdọ ọmọbinrin Jerusalemu. 9. Njẹ kini iwọ ha nkigbe soke si? ọba kò ha si ninu rẹ? awọn ìgbimọ rẹ ṣegbé bi? nitori irora ti dì ọ mu bi obinrin ti nrọbi. 10. Ma rọbi, si bi, ọmọbinrin Sioni, bi ẹniti nrọbi: nitori nisisiyi ni iwọ o jade lọ kuro ninu ilu, iwọ o si ma gbe inu igbẹ́, iwọ o si lọ si Babiloni; nibẹ̀ ni a o gbà ọ; nibẹ̀ ni Oluwa yio rà ọ padà kuro lọwọ awọn ọta rẹ. 11. Ati nisisiyi ọ̀pọlọpọ orile-ède gbá jọ si ọ, ti nwi pe, jẹ ki a sọ ọ di aimọ́, si jẹ ki oju wa ki o wo Sioni. 12. Ṣugbọn nwọn kò mọ̀ erò Oluwa, bẹ̃ni oye ìmọ rẹ̀ kò ye wọn: nitori on o kó wọn jọ bi ití sinu ipaka. 13. Dide, si ma pakà, Iwọ ọmọbinrin Sioni: nitori emi o sọ iwo rẹ di irin, emi o si sọ patakò rẹ di idẹ, iwọ o si run ọ̀pọlọpọ enia womu-womu: emi o si yá ère wọn sọtọ̀ fun Oluwa, ati iní wọn si Oluwa gbogbo aiye.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *