We are Still Working on our Online Web Version, Kindly Check Later!

Luku 22

Àwọn Juu Dìtẹ̀ láti Pa Jesu

(Mat 26:1-5, 14-16; Mak 14:1-2, 10-11; Joh 11:45-53)

1. AJỌ ọdun aiwukara ti a npè ni Irekọja si kù fẹfẹ. 2. Ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe nwá ọ̀na bi nwọn iba ti ṣe pa a; nitoriti nwọn mbẹ̀ru awọn enia. 3. Satani si wọ̀ inu Judasi, ti a npè ni Iskariotu, ọkan ninu awọn mejila. 4. O si mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n, o lọ lati ba awọn olori alufa ati awọn olori ẹṣọ́ mọ̀ ọ pọ̀, bi on iba ti fi i le wọn lọwọ. 5. Nwọn si yọ̀, nwọn si ba a da majẹmu ati fun u li owo. 6. O si gbà: o si nwá akoko ti o wọ̀, lati fi i le wọn lọwọ laìsi ariwo.

Ìpalẹ̀mọ́ fún Àsè Ìrékọjá

(Mat 26:17-25; Mak 14:12-21; Joh 13:21-30)

7. Ọjọ aiwukara pé, nigbati nwọn kò le ṣe aiṣẹbọ irekọja. 8. O si rán Peteru on Johanu, wipe, Ẹ lọ ipèse irekọja fun wa, ki awa ki o jẹ. 9. Nwọn si wi fun u pe, Nibo ni iwọ nfẹ ki a pèse sile? 10. O si wi fun wọn pe, Kiyesi i, nigbati ẹnyin ba nwọ̀ ilu lọ, ọkunrin kan ti o rù iṣa omi yio pade nyin; ẹ ba a lọ si ile ti o ba wọ̀. 11. Ki ẹ si wi fun bãle ile na pe, Olukọni wi fun ọ pe, Nibo ni gbọ̀ngan apejẹ na gbé wà, nibiti emi o gbé jẹ irekọja pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi? 12. On o si fi gbọ̀ngan nla kan loke hàn nyin, ti a ṣe lọṣọ: nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o pèse silẹ. 13. Nwọn si lọ nwọn si bá a gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: nwọn si pèse irekọja silẹ.

Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa

(Mat 26:26-30; Mak 14:22-26; 1 Kọr 11:23-25)

14. Nigbati akokò si to, o joko ati awọn aposteli pẹlu rẹ̀. 15. O si wi fun wọn pe, Tinu-tinu li emi fẹ fi ba nyin jẹ irekọja yi, ki emi ki o to jìya: 16. Nitori mo wi fun nyin, Emi kì yio jẹ ninu rẹ̀ mọ́, titi a o fi mú u ṣẹ ni ijọba Ọlọrun. 17. O si gbà ago, nigbati o si ti dupẹ, o wipe, Gbà eyi, ki ẹ si pín i larin ara nyin. 18. Nitori mo wi fun nyin, Emi kì yio mu ninu eso ajara mọ́, titi ijọba Ọlọrun yio fi de. 19. O si mú akara, nigbati o si ti dupẹ o bu u, o si fifun wọn, o wipe, Eyi li ara mi ti a fifun nyin: ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi. 20. Bẹ̃ gẹgẹ lẹhin onjẹ alẹ, o si mu ago, o wipe, Ago yi ni majẹmu titun li ẹ̀jẹ mi, ti a ta silẹ fun nyin. 21. Ṣugbọn ẹ kiyesi i, ọwọ́ ẹniti o fi mi hàn wà pẹlu mi lori tabili. 22. Ọmọ-enia nlọ nitõtọ bi a ti pinnu rẹ̀: ṣugbọn egbé ni fun ọkunrin na nipasẹ ẹniti a gbé ti fi i hàn! 23. Nwọn si bẹ̀rẹ si ibère larin ara wọn, tani ninu wọn ti yio ṣe nkan yi. 24. Ijà kan si mbẹ larin wọn, niti ẹniti a kà si olori ninu wọn. 25. O si wi fun wọn pe, Awọn ọba Keferi a ma fẹla lori wọn: a si ma pè awọn alaṣẹ wọn ni olõre. 26. Ṣugbọn ẹnyin kì yio ri bẹ̃: ṣugbọn ẹniti o ba pọ̀ju ninu nyin ki o jẹ bi aburo; ẹniti o si ṣe olori, bi ẹniti nṣe iranṣẹ. 27. Nitori tali o pọ̀ju, ẹniti o joko tì onjẹ, tabi ẹniti o nṣe iranṣẹ? ẹniti o joko tì onjẹ ha kọ́? ṣugbọn emi mbẹ larin nyin bi ẹniti nṣe iranṣẹ. 28. Ẹnyin li awọn ti o ti duro tì mi ninu idanwo mi. 29. Mo si yàn ijọba fun nyin, gẹgẹ bi Baba mi ti yàn fun mi; 30. Ki ẹnyin ki o le mã jẹ, ki ẹnyin ki o si le mã mu lori tabili mi ni ijọba mi, ki ẹnyin ki o le joko lori itẹ́, ati ki ẹnyin ki o le mã ṣe idajọ fun awọn ẹ̀ya Israeli mejila.

Jesu Sọtẹ́lẹ̀ pé Peteru Yóo Sẹ́ Òun

(Mat 26:31-35; Mak 14:27-31; Joh 13:36-38)

31. Oluwa si wipe, Simoni, Simoni, sawõ, Satani fẹ lati ni ọ, ki o le kù ọ bi alikama: 32. Ṣugbọn mo ti gbadura fun ọ, ki igbagbọ́ rẹ ki o má yẹ̀; ati iwọ nigbati iwọ ba si yipada, mu awọn arakunrin rẹ li ọkàn le. 33. O si wi fun u pe, Oluwa, mo mura tan lati bá ọ lọ sinu tubu, ati si ikú. 34. O si wipe, Mo wi fun ọ, Peteru, akukọ ki yio kọ loni ti iwọ o fi sẹ́ mi li ẹrinmẹta pe, iwọ kò mọ̀ mi.

Idà Meji

35. O si wi fun wọn pe, Nigbati mo rán nyin lọ laini asuwọn, ati àpo, ati bàta, ọdá ohun kan da nyin bi? Nwọn si wipe, Rara o. 36. Nigbana li o wi fun wọn pe, Ṣugbọn nisisiyi, ẹniti o ba li asuwọn, ki o mu u, ati àpo pẹlu: ẹniti kò ba si ni idà, ki o tà aṣọ rẹ̀, ki o si fi rà kan. 37. Nitori mo wi fun nyin pe, Eyi ti a ti kọwe rẹ̀ kò le ṣe ki o má ṣẹ lara mi, A si kà a mọ awọn arufin. Nitori ohun wọnni nipa ti emi o li opin. 38. Nwọn si wipe, Oluwa, sawõ, idà meji mbẹ nihinyi. O si wi fun wọn pe, O to.

Adura Lórí Òkè Olifi

(Mat 26:36-46; Mak 14:32-42)

39. O si jade, o si lọ bi iṣe rẹ̀ si òke Olifi; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ lẹhin. 40. Nigbati o wà nibẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹ mã gbadura, ki ẹnyin ki o máṣe bọ sinu idẹwò. 41. O si fi wọn silẹ niwọn isọko kan, o si kunlẹ o si ngbadura, 42. Wipe, Baba, bi iwọ ba fẹ, gbà ago yi lọwọ mi: ṣugbọn ifẹ ti emi kọ́, bikoṣe tirẹ ni ki a ṣe. 43. Angẹli kan si yọ si i lati ọrun wá, o ngbà a ni iyanju. 44. Bi o si ti wà ni iwaya-ija o ngbadura si i kikankikan: õgùn rẹ̀ si dabi iro ẹ̀jẹ nla, o nkán silẹ. 45. Nigbati o si dide kuro ni ibi adura, ti o si tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o ba wọn, nwọn nsùn fun ibanujẹ, 46. O si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nsùn si? ẹ dide, ẹ mã gbadura, ki ẹnyin ki o máṣe bọ́ sinu idẹwò.

Judasi Fi Jesu fún Àwọn Ọ̀tá

(Mat 26:47-56; Mak 14:43-50; Joh 18:3-11)

47. Bi o si ti nsọ lọwọ, kiyesi i, ọ̀pọ enia, ati ẹniti a npè ni Judasi, ọkan ninu awọn mejila, o ṣaju wọn o sunmọ Jesu lati fi ẹnu kò o li ẹnu. 48. Jesu si wi fun u pe, Judasi, iwọ fi ifẹnukonu fi Ọmọ-enia hàn? 49. Nigbati awọn ti o wà lọdọ rẹ̀ ri bi yio ti jasi, nwọn bi i pe, Oluwa, ki awa ki o fi idà ṣá wọn? 50. Ọkan ninu wọn si fi idà ṣá ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke etí ọtún rẹ̀ sọnù. 51. Ṣugbọn Jesu dahùn o wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀ bayi na. O si fi ọwọ́ tọ́ ọ li etí, o si wò o sàn. 52. Jesu si wi fun awọn olori alufa, ati awọn olori ẹṣọ́ tẹmpili, ati awọn agbagba, ti nwọn jade tọ̀ ọ wá, pe, Ẹnyin ha jade wá ti ẹnyin ti idà ati ọgọ bi ẹni tọ ọlọṣa wá? 53. Nigbati emi wà pẹlu nyin lojojumọ ni tẹmpili, ẹnyin ko nà ọwọ́ mu mi: ṣugbọn akokò ti nyin li eyi, ati agbara òkunkun.

Judasi Fi Jesu fún Àwọn Ọ̀tá

(Mat 26:47-56; Mak 14:43-50; Joh 18:3-11)

54. Nwọn si gbá a mu, nwọn si fà a lọ, nwọn si mu u wá si ile olori alufa. Ṣugbọn Peteru tọ̀ ọ lẹhin li òkere. 55. Nigbati nwọn si ti dana larin gbọ̀ngan, ti nwọn si joko pọ̀, Peteru joko larin wọn. 56. Ọmọbinrin kan si ri i bi o ti joko nibi imọlẹ iná na, o si tẹjumọ́ ọ, o ni, Eleyi na wà pẹlu rẹ̀. 57. O si sẹ́, o wipe, Obinrin yi, emi ko mọ̀ ọ. 58. Kò pẹ lẹhin na ẹlomiran si ri i, o ni, Iwọ pẹlu wà ninu wọn. Ṣugbọn Peteru wipe, ọkunrin yi, Emi kọ. 59. O si to iwọn wakati kan ẹlomiran gidigidi tẹnumọ́ ọ, nwipe, Nitõtọ eleyi na wà pẹlu rẹ̀: nitori ara Galili ni iṣe. 60. Ṣugbọn Peteru wipe, ọkunrin yi, emi kò mọ̀ ohun ti iwọ nwi. Lojukanna, bi o ti nwi li ẹnu, akukọ kọ. 61. Oluwa si yipada, o wò Peteru. Peteru si ranti ọ̀rọ Oluwa, bi o ti wi fun u pe, Ki akukọ ki o to kọ, iwọ o sẹ́ mi li ẹrinmẹta. 62. Peteru si bọ si ode, o sọkun kikorò.

Wọ́n Fi Jesu Ṣẹ̀sín

(Mat 26:67-68; Mak 14:65)

63. Awọn ọkunrin ti nwọn mu Jesu, si fi i ṣe ẹlẹyà, nwọn lù u. 64. Nigbati nwọn si dì i loju, nwọn lù u niwaju, nwọn mbi i pe, Sọtẹlẹ, tani lù ọ nì? 65. Ati nkan pipọ miran ni nwọn nfi ọ̀rọ-òdi sọ si i.

Wọ́n Mú Jesu Lọ Siwaju Ìgbìmọ̀

(Mat 26:59-66; Mak 14:55-64; Joh 18:19-24)

66. Nigbati ilẹ si mọ́, awọn àgba awọn enia, ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe pejọ, nwọn si fà a wá si ajọ wọn, nwọn nwipe, 67. Bi iwọ ba iṣe Kristi na? sọ fun wa. O si wi fun wọn pe, Bi mo ba wi fun nyin, ẹnyin ki yio gbagbọ́: 68. Bi mo ba si bi nyin lẽre pẹlu, ẹnyin kì yio da mi lohùn, bẹ̃li ẹnyin kì yio jọwọ mi lọwọ lọ. 69. Ṣugbọn lati isisiyi lọ li Ọmọ-enia yio joko li ọwọ́ ọtún agbara Ọlọrun. 70. Gbogbo wọn si wipe, Iwọ ha ṣe Ọmọ Ọlọrun bi? O si wi fun wọn pe, Ẹnyin wipe, emi ni. 71. Nwọn si wipe, Kili awa nfẹ ẹlẹri mọ́ si? Awa tikarawa sá ti gbọ́ li ẹnu ara rẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *