We are Still Working on our Online Web Version, Kindly Check Later!

Lefitiku 24

Ìtọ́jú Àwọn Fìtílà

(Eks 27:20-21)

1. OLUWA si sọ fun Mose pe, 2. Fi aṣẹ fun awọn ọmọ Israeli pe, ki nwọn ki o mú oróro daradara ti olifi gigún fun ọ wá, fun imọlẹ lati ma mu fitila jó nigbagbogbo. 3. Lẹhin ode aṣọ-ikele ẹrí, ninu agọ́ ajọ, ni ki Aaroni ki o tọju rẹ̀ lati aṣalẹ di owurọ̀ nigbagbogbo niwaju OLUWA: ìlana ni titilai ni iran-iran nyin. 4. Ki o si tọju fitila lori ọpá-fitila mimọ́ nì nigbagbogbo niwaju OLUWA.

Àkàrà Tí Wọ́n Fi Rúbọ sí Ọlọrun

5. Ki iwọ ki o si mú iyẹfun daradara, ki o si yan ìṣu-àkara mejila ninu rẹ̀: idamẹwa meji òṣuwọn ni ki o wà ninu ìṣu-àkara kan. 6. Ki iwọ ki o si tò wọn li ẹsẹ meji, mẹfa li ẹsẹ kan, lori tabili mimọ́ niwaju OLUWA. 7. Ki iwọ ki o si fi turari daradara sori ẹsẹ̀ kọkan ki o le wà lori ìṣu-àkara na fun iranti, ani ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA. 8. Li ọjọjọ́ isimi ni ki ẹ ma tun u tò niwaju OLUWA titi; gbigbà ni lọwọ awọn ọmọ Israeli nipa majẹmu titi aiye. 9. Ki o si ma jẹ́ ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ; ki nwọn ki o si ma jẹ ẹ ni ibi mimọ́ kan: nitoripe mimọ́ julọ ni fun u ninu ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, ìlana titilai.

Àpẹẹrẹ Ìdájọ́ ati Ìjẹníyà Tí Ó Tọ́

10. Ati ọmọkunrin obinrin Israeli kan, ti baba rẹ̀ ṣe ara Egipti, o jade lọ ninu awọn ọmọ Israeli: ọmọkunrin obinrin Israeli yi ati ọkunrin Israeli kan si jà ni ibudó. 11. Eyi ọmọkunrin obinrin Israeli yi, sọ̀rọ buburu si Orukọ nì, o si fi bú: nwọn si mú u tọ̀ Mose wá. Orukọ iya rẹ̀ ama jẹ Ṣelomiti, ọmọbinrin Dibri, ti ẹ̀ya Dani. 12. Nwọn si ha a mọ́ ile-ìde, titi a o fi fi inu OLUWA hàn fun wọn. 13. OLUWA si sọ fun Mose pe, 14. Mú ẹniti o ṣe ifibu nì wá sẹhin ibudó; ki gbogbo awọn ti o si gbọ́ ọ ki o fi ọwọ́ wọn lé ori rẹ̀, ki gbogbo ijọ enia ki o le sọ ọ li okuta. 15. Ki iwọ ki o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnikẹni ti o ba fi Ọlọrun rẹ̀ bú yio rù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. 16. Ati ẹniti o sọ̀rọ buburu si orukọ OLUWA nì, pipa ni ki a pa a: gbogbo ijọ enia ni ki o sọ ọ li okuta pa nitõtọ: ati alejò, ati ibilẹ, nigbati o ba sọ̀rọbuburu si orukọ OLUWA, pipa li a o pa a. 17. Ati ẹniti o ba gbà ẹmi enia, pipa li a o pa a: 18. Ẹniti o ba si lù ẹran kan pa, ki o san a pada: ẹmi fun ẹmi. 19. Bi ẹnikan ba si ṣe abùku kan si ara ẹnikeji rẹ̀; bi o ti ṣe, bẹ̃ni ki a ṣe si i; 20. Ẹ̀ya fun ẹ̀ya, oju fun oju, ehin fun ehin; bi on ti ṣe abùku si ara enia, bẹ̃ni ki a ṣe si i. 21. Ẹniti o ba si lù ẹran pa, ki o san a pada: ẹniti o ba si lù enia pa, a o pa a. 22. Irú ofin kan li ẹnyin o ní, gẹgẹ bi fun alejò bẹ̃ni fun ibilẹ: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 23. Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli, pe ki nwọn ki o mú ẹniti o ṣe ifibu nì jade lọ sẹhin ibudó, ki nwọn ki o si sọ ọ li okuta pa. Awọn ọmọ Israeli si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *