We are Still Working on our Online Web Version, Kindly Check Later!

Lefitiku 19

Àwọn Òfin Tí Wọ́n Jẹmọ́ Ẹ̀tọ́ ati Jíjẹ́ Mímọ́

1. OLUWA si sọ fun Mose pe, 2. Sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Ki ẹnyin ki o jẹ́ mimọ́: nitoripe Emi OLUWA Ọlọrun nyin jẹ́ mimọ́. 3. Ki olukuluku nyin ki o bẹ̀ru iya rẹ̀, ati baba rẹ̀, ki o si ma pa ọjọ́ isimi mi mọ́: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 4. Ẹ máṣe yipada si ere, bẹ̃ni ki ẹnyin má si ṣe ṣe oriṣa didà fun ara nyin: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 5. Bi ẹnyin ba si ru ẹbọ alafia si OLUWA, ki ẹnyin ki o ru u ki ẹ le di ẹni itẹwọgbà. 6. Li ọjọ́ ti ẹnyin ru ẹbọ na ni ki a jẹ ẹ, ati ni ijọ́ keji: bi ohun kan ba si kù ninu rẹ̀ titi di ijọ́ kẹta, ninu iná ni ki a sun u. 7. Bi a ba si jẹ ninu rẹ̀ rára ni ijọ́ kẹta, irira ni; ki yio dà: 8. Nitorina ẹniti o ba jẹ ẹ ni yio rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀, nitoriti o bà ohun mimọ́ OLUWA jẹ́: ọkàn na li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀. 9. Ati nigbati ẹnyin ba nṣe ikore ilẹ nyin, iwọ kò gbọdọ ṣa igun oko rẹ li aṣatán, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ pa èṣẹ́ ikore rẹ. 10. Iwọ kò si gbọdọ pèṣẹ́ ọgbà-àjara rẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ká gbogbo àjara ọgbà-àjara rẹ; ki iwọ ki o fi wọn silẹ fun awọn talaka ati alejò: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 11. Ẹnyin kò gbọdọ jale, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣe alaiṣõtọ, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣeké fun ara nyin. 12. Ẹnyin kò si gbọdọ fi orukọ mi bura eké, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bà orukọ Ọlọrun rẹ jẹ́: Emi li OLUWA. 13. Iwọ kò gbọdọ rẹ́ ẹnikeji rẹ jẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jẹ haramu: owo ọ̀ya alagbaṣe kò gbọdọ sùn ọdọ rẹ titi di owurọ̀. 14. Iwọ kò gbọdọ bú aditi, tabi ki o fi ohun idugbolu siwaju afọju, ṣugbọn ki iwọ ki o bẹ̀ru Ọlọrun rẹ: Emi li OLUWA. 15. Ẹnyin kò gbọdọ ṣe aiṣododo ni idajọ: iwọ kò gbọdọ gbè talaka, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣe ojusaju alagbara: li ododo ni ki iwọ ki o mã ṣe idajọ ẹnikeji rẹ. 16. Iwọ kò gbọdọ lọ soke lọ sodo bi olofófo lãrin awọn enia rẹ: bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ró tì ẹ̀jẹ ẹnikeji rẹ: Emi li OLUWA. 17. Iwọ kò gbọdọ korira arakunrin rẹ li ọkàn rẹ: ki iwọ ki o bá ẹnikeji rẹ wi, ki iwọ ki o máṣe jẹbi nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 18. Iwọ kò gbọdọ gbẹsan, bẹ̃ni ki o máṣe ṣe ikùnsinu si awọn ọmọ enia rẹ, ṣugbọn ki iwọ ki o fẹ́ ẹnikeji rẹ bi ara rẹ: Emi li OLUWA. 19. Ki ẹnyin ki o pa ìlana mi mọ́. Iwọ kò gbọdọ jẹ ki ẹranọ̀sin rẹ ki o ba onirũru dàpọ: iwọ kò gbọdọ fọ́n daru-dàpọ irugbìn si oko rẹ: bẹ̃li aṣọ ti a fi ọ̀gbọ ati kubusu hun pọ̀ kò gbọdọ kan ara rẹ. 20. Ati ẹnikẹni ti o ba bá obinrin dàpọ, ti iṣe ẹrú, ti a fẹ́ fun ọkọ, ti a kò ti ràpada rára, ti a kò ti sọ di omnira; ọ̀ran ìna ni; ki a máṣe pa wọn, nitoriti obinrin na ki iṣe omnira. 21. Ki ọkunrin na ki o si mú ẹbọ ẹbi rẹ̀ wá fun OLUWA, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ani àgbo kan fun ẹbọ ẹbi. 22. Ki alufa ki o si fi àgbo ẹbọ ẹbi ṣètutu fun u niwaju OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o da: a o si dari ẹ̀ṣẹ ti o da jì i. 23. Ati nigbati ẹnyin o ba si dé ilẹ na, ti ẹnyin o si gbìn onirũru igi fun onjẹ, nigbana ni ki ẹnyin kà eso rẹ̀ si alaikọlà: li ọdún mẹta ni ki o jasi bi alaikọlà fun nyin; ki a máṣe jẹ ẹ. 24. Ṣugbọn li ọdún kẹrin, gbogbo eso rẹ̀ na ni yio jẹ́ mimọ́, si ìyin OLUWA. 25. Ati li ọdún karun ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu eso rẹ̀, ki o le ma mú ibisi rẹ̀ wá fun nyin: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 26. Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ohun kan ti on ti ẹ̀jẹ: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣe ifaiya, tabi ṣe akiyesi ìgba. 27. Ẹnyin kò gbọdọ gẹ̀ ori nyin, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ tọ́ irungbọn rẹ. 28. Ẹnyin kò gbọdọ sín gbẹ́rẹ kan si ara nyin nitori okú, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ kọ àmi kan si ara nyin: Emi li OLUWA. 29. Máṣe bà ọmọ rẹ obinrin jẹ́, lati mu u ṣe àgbere; ki ilẹ na ki o má ba di ilẹ àgbere, ati ki ilẹ na má ba kún fun ìwabuburu. 30. Ki ẹnyin ki o si ma pa ọjọ́ isimi mi mọ́, ki ẹnyin ki o si bọ̀wọ fun ibi mimọ́ mi: Emi li OLUWA. 31. Máṣe yipada tọ̀ awọn ti o ní ìmọ afọṣẹ, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o má si ṣe wá ajẹ́ kiri, lati fi wọn bà ara nyin jẹ́: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 32. Ki iwọ ki o si dide duro niwaju ori-ewú, ki o si bọ̀wọ fun oju arugbo, ki o si bẹ̀ru Ọlọrun rẹ: Emi li OLUWA. 33. Ati bi alejò kan ba nṣe atipo pẹlu rẹ ni ilẹ nyin, ẹnyin kò gbọdọ ni i lara. 34. Ki alejò ti mbá nyin gbé ki o jasi fun nyin bi ibilẹ, ki iwọ ki o si fẹ́ ẹ bi ara rẹ; nitoripe ẹnyin ti ṣe alejò ni ilẹ Egipti: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin. 35. Ẹnyin kò gbọdọ ṣe aiṣododo ni idajọ, ni ìwọn ọpá, ni òṣuwọn iwuwo, tabi ni òṣuwọn oninu. 36. Oṣuwọn otitọ, òṣuwọn iwuwo otitọ, òṣuwọn efa otitọ, ati òṣuwọn hini otitọ, ni ki ẹnyin ki o ní: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá. 37. Nitorina ni ki ẹnyin ki o si ma kiyesi gbogbo ìlana mi, ati si gbogbo idajọ mi, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: Emi li OLUWA.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *