We are Still Working on our Online Web Version, Kindly Check Later!

Lefitiku 10

Ẹ̀ṣẹ̀ Nadabu ati Abihu

1. ATI Nadabu ati Abihu, awọn ọmọ Aaroni, olukuluku nwọn mú awo-turari rẹ̀, nwọn si fi iná sinu wọn, nwọn si fi turari sori wọn, nwọn si mú ajeji iná wá siwaju OLUWA, ti on kò fi aṣẹ fun wọn. 2. Iná si ti ọdọ OLUWA jade, o si run wọn, nwọn si kú niwaju OLUWA. 3. Nigbana ni Mose wi fun Aaroni pe, Eyiyi li OLUWA wipe, A o yà mi simimọ́ ninu awọn ti nsunmọ mi, ati niwaju awọn enia gbogbo li a o yìn mi li ogo. Aaroni si dakẹ. 4. Mose si pé Miṣaeli ati Elsafani, awọn ọmọ Usieli arakunrin Aaroni, o si wi fun wọn pe, Ẹ sunmọ ihin, ẹ gbé awọn arakunrin nyin kuro niwaju ibi mimọ́ jade sẹhin ibudó. 5. Bẹ̃ni nwọn sunmọ ibẹ̀, nwọn si gbé ti awọn ti ẹ̀wu wọn jade sẹhin ibudó; bi Mose ti wi. 6. Mose si wi fun Aaroni, ati fun Eleasari ati fun Itamari, awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ máṣe ṣi ibori nyin, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fà aṣọ nyin ya; ki ẹnyin ki o má ba kú, ati ki ibinu ki o má ba wá sori gbogbo ijọ: ṣugbọn ki awọn arakunrin nyin, gbogbo ile Israeli ki o sọkun ijóna ti OLUWA ṣe yi. 7. Ki ẹnyin ki o má si ṣe jade kuro lati ibi ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ki ẹnyin ki o má ba kú: nitoripe oróro itasori OLUWA mbẹ lara nyin. Nwọn si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose.

Òfin fún Àwọn Àlùfáàa

8. OLUWA si sọ fun Aaroni pe, 9. Máṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, iwọ, tabi awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ, nigbati ẹnyin ba wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, ki ẹnyin ki o má ba kú: ìlana ni titilai ni iraniran nyin: 10. Ki ẹnyin ki o le ma fi ìyatọ sãrin mimọ́ ati aimọ́, ati sãrin ẽri ati ailẽri; 11. Ati ki ẹnyin ki o le ma kọ́ awọn ọmọ Israeli ni gbogbo ìlana ti OLUWA ti sọ fun wọn lati ọwọ́ Mose wá. 12. Mose si wi fun Aaroni, ati fun Eleasari ati fun Itamari, awọn ọmọ rẹ̀ ti o kù pe, Ẹ mú ẹbọ ohunjijẹ ti o kù ninu ẹbọ OLUWA, ti a fi iná ṣe, ki ẹ si jẹ ẹ lainí iwukàra lẹba pẹpẹ: nitoripe mimọ́ julọ ni: 13. Ki ẹnyin ki o si jẹ ẹ ni ibi mimọ́, nitoripe ipín tirẹ, ati ipín awọn ọmọ rẹ ni, ninu ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: nitoripe, bẹ̃li a fi aṣẹ fun mi. 14. Ati igẹ̀ fifì, ati itan agbesọsoke ni ki ẹnyin ki o jẹ ni ibi mimọ́ kan; iwọ, ati awọn ọmọkunrin rẹ, ati awọn ọmọbinrin rẹ pẹlu rẹ: nitoripe ipín tirẹ ni, ati ipín awọn ọmọ rẹ, ti a fi fun nyin ninu ẹbọ alafia awọn ọmọ Israeli. 15. Itan agbesọsoke ati igẹ̀ fifì ni ki nwọn ki o ma múwa pẹlu ẹbọ ti a fi iná ṣe ti ọrá, lati fì i fun ẹbọ fifì niwaju OLUWA: yio si ma jẹ́ tirẹ, ati ti awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ, nipa ìlana titilai; bi OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ. 16. Mose si fi pẹlẹpẹlẹ wá ewurẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì, si kiyesi i, a ti sun u: o si binu si Eleasari ati Itamari, awọn ọmọ Aaroni ti o kù, wipe, 17. Nitori kini ẹnyin kò ṣe jẹ ẹbọ èṣẹ na ni ibi mimọ́, nitoripe mimọ́ julọ ni, a si ti fi fun nyin lati rù ẹ̀ṣẹ ijọ enia, lati ṣètutu fun wọn niwaju OLUWA? 18. Kiyesi i, a kò mú ẹ̀jẹ rẹ̀ wá sinu ibi mimọ́: ẹnyin iba ti jẹ ẹ nitõtọ ni ibi mimọ́, bi mo ti paṣẹ. 19. Aaroni si wi fun Mose pe, Kiyesi i, li oni ni nwọn ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn ati ẹbọ sisun wọn niwaju OLUWA; irú nkan wọnyi li o si ṣubulù mi: emi iba si ti jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ li oni, o ha le dara li oju OLUWA? 20. Nigbati Mose gbọ́ eyi inu rẹ̀ si tutù.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *