We are Still Working on our Online Web Version, Kindly Check Later!

Genesisi 35

Ọlọrun Súre fún Jakọbu ní Bẹtẹli

1. ỌLỌRUN si wi fun Jakobu pe, Dide goke lọ si Beteli ki o si joko nibẹ̀, ki o si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, fun Ọlọrun, ti o farahàn ọ, nigbati iwọ sá kuro niwaju Esau, arakunrin rẹ. 2. Nigbana ni Jakobu wi fun awọn ara ile rẹ̀, ati fun gbogbo awọn ti o wà li ọdọ rẹ̀ pe, Ẹ mú àjeji oriṣa ti o wà lọwọ nyin kuro, ki ẹnyin ki o si sọ ara nyin di mimọ́, ki ẹnyin ki o si pa aṣọ nyin dà: 3. Ẹ si jẹ ki a dide, ki a si goke lọ si Beteli; nibẹ̀ li emi o si gbé tẹ́ pẹpẹ kan fun Ọlọrun ti o da mi li ohùn li ọjọ́ ipọnju mi, ẹniti o si wà pẹlu mi li àjo ti mo rè. 4. Nwọn si fi gbogbo àjeji oriṣa ti o wà lọwọ wọn fun Jakobu, ati gbogbo oruka eti ti o wà li eti wọn: Jakobu si pa wọn mọ́ li abẹ igi oaku ti o wà leti Ṣekemu. 5. Nwọn si rìn lọ: ẹ̀ru Ọlọrun si mbẹ lara ilu ti o yi wọn ká, nwọn kò si lepa awọn ọmọ Jakobu. 6. Bẹ̃ni Jakobu si wá si Lusi, ti o wà ni ilẹ Kenaani, eyinì ni Beteli, on ati gbogbo enia ti o wà lọdọ rẹ̀. 7. O si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀, o si sọ orukọ ibẹ̀ na ni El-bet-el: nitori pe nibẹ̀ li Ọlọrun tọ̀ ọ wá, nigbati o sá kuro niwaju arakunrin rẹ̀. 8. Ṣugbọn Debora olutọ́ Rebeka kú, a si sin i nisalẹ Beteli labẹ igi oaku kan: orukọ rẹ̀ a si ma jẹ́ Alloni-bakutu. 9. Ọlọrun si tún farahàn Jakobu, nigbati o ti Padan-aramu bọ̀, o si sure fun u. 10. Ọlọrun si wi fun u pe, Jakobu li orukọ rẹ: a ki yio pè orukọ rẹ ni Jakobu mọ́, bikoṣe Israeli li orukọ rẹ yio ma jẹ́: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Israeli. 11. Ọlọrun si wi fun u pe, Emi li Ọlọrun Olodumare: ma bisi i, si ma rẹ̀; orilẹ-ède, ati ẹgbẹ-ẹgbẹ orilẹ-ède ni yio ti ọdọ rẹ wá, awọn ọba yio si ti inu rẹ jade wá; 12. Ati ilẹ ti mo ti fi fun Abrahamu ati Isaaki, iwọ li emi o fi fun, ati irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ li emi o fi ilẹ na fun. 13. Ọlọrun si lọ soke kuro lọdọ rẹ̀ ni ibi ti o gbé mbá a sọ̀rọ. 14. Jakobu si fi ọwọ̀n kan lelẹ ni ibi ti o gbé bá a sọ̀rọ, ani ọwọ̀n okuta: o si ta ọrẹ ohun mimu si ori rẹ̀, o si ta oróro si ori rẹ̀. 15. Jakobu si sọ orukọ ibi ti Ọlọrun gbé bá a sọ̀rọ ni Beteli.

Ikú Rakẹli

16. Nwọn si rìn lati Beteli lọ; o si kù diẹ ki nwọn ki o dé Efrati: ibi si tẹ̀ Rakeli: o si ṣoro jọjọ fun u. 17. O si ṣe nigbati o wà ninu irọbí, ni iyãgba wi fun u pe, Máṣe bẹ̀ru: iwọ o si li ọmọkunrin yi pẹlu. 18. O si ṣe, bi ọkàn rẹ̀ ti nlọ̀ (o sa kú) o sọ orukọ rẹ̀ ni Ben-oni: ṣugbọn baba rẹ̀ sọ ọ ni Benjamini. 19. Rakeli si kú, a si sin i li ọ̀na Efrati, ti iṣe Betlehemu. 20. Jakobu si fi ọwọ̀n kan lelẹ li oju-õri rẹ̀, eyinì ni Ọwọ̀n oju-õri Rakeli titi di oni-oloni. 21. Israeli si nrìn lọ, o si pa agọ́ rẹ̀ niwaju ile iṣọ Ederi.

Àwọn Ọmọ Jakọbu

(1 Kron 2:1-2)

22. O si ṣe nigbati Israeli joko ni ilẹ na, Reubeni si wọle tọ̀ Bilha, àle baba rẹ̀ lọ; Israeli si gbọ́. Njẹ awọn ọmọ Jakobu jẹ́ mejila. 23. Awọn ọmọ Lea; Reubẹni, akọ́bi Jakobu, ati Simeoni, ati Lefi, ati Judah, ati Issakari, ati Sebuluni. 24. Awọn ọmọ Rakeli; Josefu, ati Benjamini: 25. Ati awọn ọmọ Bilha, iranṣẹbinrin Rakeli; Dani, ati Naftali: 26. Ati awọn ọmọ Silpa, iranṣẹbinrin Lea; Gadi ati Aṣeri. Awọn wọnyi li ọmọ Jakobu, ti a bí fun u ni Padanaramu.

Ikú Isaaki

27. Jakobu si dé ọdọ Isaaki baba rẹ̀, ni Mamre, si Kiriat-arba, ti iṣe Hebroni, nibiti Abrahamu ati Isaaki gbé ṣe atipo pẹlu. 28. Ọjọ́ Isaaki si jẹ́ ọgọsan ọdún. 29. Isaaki si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o si kú, a si kó o jọ pẹlu awọn enia rẹ̀, o gbó, o si kún fun ọjọ́, awọn ọmọ rẹ̀, Esau ati Jakobu si sin i.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *