We are Still Working on our Online Web Version, Kindly Check Later!

Genesisi 05

Ìwé Àkọsílẹ̀ Ìran Adamu

(1 Kron 1:1-4)

1. EYI ni iwe iran Adamu: Li ọjọ́ ti Ọlọrun dá ọkunrin, li aworan Ọlọrun li o dá a. 2. Ati akọ ati abo li o dá wọn; o si súre fun wọn, o si pè orukọ wọn ni Adamu, li ọjọ́ ti a dá wọn. 3. Adamu si wà li ãdoje ọdún, o si bí ọmọkunrin kan ni jijọ ati li aworan ara rẹ̀; o si pè orukọ rẹ̀ ni Seti: 4. Ọjọ́ Adamu, lẹhin ti o bí Seti, jẹ ẹgbẹrin ọdún: o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 5. Gbogbo ọjọ́ ti Adamu wà si jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdún o lé ọgbọ̀n: o si kú. 6. Seti si wà li ọgọrun ọdún o lé marun, o si bí Enoṣi: 7. Seti si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé meje lẹhin ti o bí Enoṣi, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 8. Ati gbogbo ọjọ́ Seti jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdun o lé mejila: o si kú. 9. Enoṣi si wà li ãdọrun ọdún, o si bí Kenani: 10. Enoṣi si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé mẹ̃dogun lẹhin ti o bí Kenani, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 11. Gbogbo ọjọ́ Enoṣi si jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdún o lé marun: o si kú. 12. Kenani si wà li ãdọrin ọdún, o si bí Mahalaleli: 13. Kenani si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé ogoji lẹhin ti o bí Mahalaleli, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 14. Gbogbo ọjọ́ Kenani si jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdún o lé mẹwa: o si kú. 15. Mahalaleli si wà li ọgọta ọdún o lé marun, o si bí Jaredi: 16. Mahalaleli si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé ọgbọ̀n, lẹhin ti o bí Jaredi, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 17. Gbogbo ọjọ́ Mahalaleli si jẹ ẹ̃dẹgbẹ̀run ọdún o dí marun: o si kú. 18. Jaredi si wà li ọgọjọ ọdún o lé meji, o si bí Enoku: 19. Jaredi si wà li ẹgbẹrin ọdún lẹhin igbati o bì Enoku, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 20. Gbogbo ọjọ́ Jaredi si jẹ ẹgbẹrun ọdún o dí mejidilogoji: o si kú. 21. Enoku si wà li ọgọta ọdún o lé marun, o si bí Metusela: 22. Enoku si ba Ọlọrun rìn li ọ̃dunrun ọdún lẹhin ti o bì Metusela, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 23. Gbogbo ọjọ́ Enoku si jẹ irinwo ọdún o dí marundilogoji: 24. Enoku si ba Ọlọrun rìn: on kò si sí; nitori ti Ọlọrun mu u lọ. 25. Metusela si wà li ọgọsan ọdún o lé meje, o si bí Lameki: 26. Metusela si wà li ẹgbẹrin ọdún o dí mejidilogun lẹhin igbati o bí Lameki, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 27. Gbogbo ọjọ́ Metusela si jẹ ẹgbẹrun ọdún o dí mọkanlelọgbọ̀n: o si kú. 28. Lameki si wà li ọgọsan ọdún o lé meji, o si bí ọmọkunrin kan: 29. O si sọ orukọ rẹ̀ ni Noa, pe, Eleyi ni yio tù wa ni inu ni iṣẹ ati lãla ọwọ́ wa, nitori ilẹ ti OLUWA ti fibú. 30. Lameki si wà li ẹgbẹta ọdún o dí marun, lẹhin ti o bí Noa, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: 31. Gbogbo ọjọ́ Lameki si jẹ ẹgbẹrin ọdún o dí mẹtalelogun: o si kú. 32. Noa si jẹ ẹni ẹ̃dẹgbẹta ọdún: Noa si bí Ṣemu, Hamu, ati Jafeti.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *