We are Still Working on our Online Web Version, Kindly Check Later!

2 Timotiu 01

1. PAULU, Aposteli Kristi Jesu nipa ifẹ Ọlọrun, gẹgẹ bi ileri ìye ti mbẹ ninu Kristi Jesu, 2. Si Timotiu, ọmọ mi olufẹ ọwọn: Ore-ọfẹ, ãnu, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Kristi Jesu Oluwa wa.

Ìdúpẹ́ ati Ọ̀rọ̀ Ìwúrí

3. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun, ti emi nsìn lati ọdọ awọn baba mi wá ninu ẹri-ọkan funfun, pe li aisimi li emi nṣe iranti rẹ ninu adura mi, 4. T'ọsan t'oru li emi njaìyà ati ri ọ, ti mo nranti omije rẹ, ki a le fi ayọ̀ kún mi li ọkàn; 5. Nigbati mo ba ranti igbagbọ́ ailẹtan ti mbẹ ninu rẹ, eyiti o kọ́ wà ninu Loide iya-nla rẹ, ati ninu Eunike iya rẹ; mo si gbagbọ pe, o mbẹ ninu rẹ pẹlu. 6. Nitori idi eyi ni mo ṣe nran ọ leti pe ki iwọ ki o mã rú ẹ̀bun Ọlọrun soke eyiti mbẹ ninu rẹ nipa gbigbe ọwọ mi le ọ. 7. Nitoripe Ọlọrun kò fun wa ni ẹmí ibẹru; bikoṣe ti agbara, ati ti ifẹ, ati ti ọkàn ti o yè kõro. 8. Nitorina máṣe tiju ẹrí Oluwa wa, tabi emi ondè rẹ̀: ṣugbọn ki iwọ ki o ṣe alabapin ninu ipọnju ihinrere gẹgẹ bi agbara Ọlọrun; 9. Ẹniti o gbà wa là, ti o si fi ìpe mimọ́ pè wa, kì iṣe gẹgẹ bi iṣe wa, ṣugbọn gẹgẹ bi ipinnu ati ore-ọfẹ tirẹ̀, ti a fifun wa ninu Kristi Jesu lati aiyeraiye, 10. Ṣugbọn ti a fihàn nisisiyi nipa ifarahàn Jesu Kristi Olugbala wa, ẹniti o pa ikú rẹ́, ti o si mu ìye ati aidibajẹ wá si imọlẹ nipasẹ ihinrere, 11. Fun eyiti a yàn mi ṣe oniwasu, ati aposteli, ati olukọ. 12. Nitori idi eyiti emi ṣe njìya wọnyi pẹlu: ṣugbọn oju kò tì mi: nitori emi mọ̀ ẹniti emi gbagbọ́, o si da mi loju pe, on le pa ohun ti mo fi le e lọwọ mọ́ titi di ọjọ nì. 13. Dì apẹrẹ awọn ọ̀rọ ti o yè koro ti iwọ ti gbọ́ lọdọ mi mu, ninu igbagbọ́ ati ifẹ ti mbẹ ninu Kristi Jesu. 14. Ohun rere nì ti a ti fi le ọ lọwọ, pa a mọ́ nipa Ẹmí Mimọ́ ti ngbe inu wa. 15. Eyi ni iwọ mọ̀, pe gbogbo awọn ti o wà ni Asia yipada kuro lẹhin mi; ninu awọn ẹniti Figellu ati Hermogene gbé wà. 16. Ki Oluwa ki o fi ãnu fun ile Onesiforu; nitoriti ima tù mi lara nigba pupọ̀, ẹ̀wọn mi kò si tì i loju: 17. Ṣugbọn nigbati o wà ni Romu, o fi ẹsọ̀ wá mi, o si ri mi. 18. Ki Oluwa ki o fifun u ki o le ri ãnu lọdọ Oluwa li ọjọ nì: iwọ tikararẹ sá mọ̀ dajudaju iye ohun ti o ṣe fun mi ni Efesu.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *