We are Still Working on our Online Web Version, Kindly Check Later!

1 Tesalonika 01

Ìkíni

1. PAULU, ati Silfanu, ati Timotiu, si ijọ awọn ara Tessalonika, ninu Ọlọrun Baba, ati ninu Jesu Kristi Oluwa: Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Jesu Kristi Oluwa.

Ìdúpẹ́

2. Awa ndupẹ lọwọ Ọlọrun nigbagbogbo fun gbogbo nyin, awa nṣe iranti nyin ninu adura wa; 3. Li aisimi li awa nranti iṣẹ igbagbọ́ nyin ati lãla ifẹ ati sũru ireti nyin ninu Oluwa wa Jesu Kristi, niwaju Ọlọrun ati Baba wa; 4. Nitoripe awa mọ yiyan nyin, ara olufẹ ti Ọlọrun, 5. Bi ihinrere wa kò ti wá sọdọ nyin li ọ̀rọ nikan, ṣugbọn li agbara pẹlu, ati ninu Ẹmí Mimọ́, ati ni ọ̀pọlọpọ igbẹkẹle; bi ẹnyin ti mọ̀ irú enia ti awa jẹ́ larin nyin nitori nyin. 6. Ẹnyin si di alafarawe wa, ati ti Oluwa, lẹhin ti ẹnyin ti gbà ọ̀rọ na ninu ipọnju ọ̀pọlọpọ, pẹlu ayọ̀ Ẹmí Mimọ́: 7. Ti ẹnyin si jẹ apẹrẹ fun gbogbo awọn ti o gbagbọ́ ni Makedonia ati Akaia. 8. Nitori lati ọdọ nyin lọ li ọ̀rọ Oluwa ti dún jade, kì iṣe ni kìki Makedonia ati Akaia nikan, ṣugbọn ni ibi gbogbo ni ìhin igbagbọ́ nyin si Ọlọrun tàn kalẹ; tobẹ̃ ti awa kò ni isọ̀rọ ohunkohun. 9. Nitoripe awọn tikarawọn ròhin nipa wa, irú iwọle ti awa ti ni sọdọ nyin, bi ẹnyin si ti yipada si Ọlọrun kuro ninu ère lati mã sìn Ọlọrun alãye ati otitọ; 10. Ati lati duro dè Ọmọ rẹ̀ lati ọrun wá, ẹniti o si ji dide kuro ninu okú, ani Jesu na, ẹniti ngbà wa kuro ninu ibinu ti mbọ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *